Ọwọ Amọtẹkun tẹ ajinigbe mọkandinlogun l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 18, 2024

Ọwọ Amọtẹkun tẹ ajinigbe mọkandinlogun l'Ondo


Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ondo ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi mọkandinlogun kan ti wọn ko niṣẹ meji ju ijinigbe lọ.
 
Yatọ si awọn mọkandinlogun yii, Amọtẹkun tun sọ pe ọwọ tẹ awọn mẹtadinlogun miran lori ẹsun ọdaran loriṣiriṣi kaakiri ipinlẹ naa.
 
Gẹgẹ bi alakoso agba fun ẹṣọ aabo ọhun, Adetunji Adelẹyẹ ṣe ṣalaye, o ni agbegbe ẹkun Ariwa ipinlẹ naa lọwọ ti tẹ gbogbo awọn afurasi ajinigbe ọhun.
 
Lakoko to n foju awọn afurasi ọdaran naa han fawọn akọroyin niluu Akurẹ, Adelẹyẹ jẹ ko di mimọ pe kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo lawọn ti ko awọn ẹṣọ ogun wọn si fun aabo to pe ye.
 
O rọ awọn araalu, to fi mọ awọn ọba alaye lati maa wa ni ikiyesara ni gbogbo igba, ati pe ki wọn ma ṣe gboju fo awọn oju tuntun ti wọn ba n kofiri lagbegbe wọn, paapaa lawọn inu igbo wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI