Ipa rere ti Alaaji Salman fi le'lẹ ko le parẹ lai - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, January 8, 2024

Ipa rere ti Alaaji Salman fi le'lẹ ko le parẹ lai - Gomina AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe ipa rere ti Oloogbe Alaaji Aliyu Alarape Salman fi le'lẹ ko too ku ko le parẹ lailai.

AbdulRazaq nigba to kẹdun iku baba naa ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye fi sita lo ti sọ pe adanu nla ni iku ọhun jẹ.

O ni oloogbe naa ti fi ipa rere le'lẹ, bẹẹ lo tun ni ipa ninu ilọsiwaju awọn agbegbe ati ipinlẹ naa.

Alaaji Salman to ti figba kan ri jẹ Kọmiṣanna f'ọrọ eto idajọ ati adajọ agba n'ipinlẹ Kwara lo jade laye laipẹ yii

Gomina AbdulRazaq ti ba  Emir ilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari, ati awọn ọmọ ẹgbẹ Ilorin Emirate Descendants Progressive Union (IEDPU), ati ẹgbẹ awọn amofin ni Naijiria, Nigerian Bar Association (NBA) kẹdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI