Nibi ti Sanjọ ti n tun 'Freezer' ṣe lo ti gan mọ ina l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 8, 2024

Nibi ti Sanjọ ti n tun 'Freezer' ṣe lo ti gan mọ ina l'Ogun


Sanjọ Adeọsun ti wọn lo yan iṣẹ awọn to n tun ẹrọ amohuntutu ati amuletutu, Freezer ṣe ni wọn sọ pe o ti gan mọ ina mọnamọna, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Adugbo kan ti wọn pe ni Power to wa lagbegbe Abule-Iroko, ipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Amos Alexander lo pe Sanjọ lati wa ba a tun firiisa rẹ ṣe, ṣugbọn to jẹ pe nibi to ti n ṣe e lọwọ ni ina ti gbe e, to si ku loju ẹsẹ.
 
Amos lo gba teṣan ọlọpaa Sango-Ọta lọ lati fi to wọn leti.
 
Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa l'Ogun nigba to n fidi rẹ mulẹ ṣalaye pe otitọ ni, ati pe wọn ti gbe oku rẹ lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa ni Ifọ fun ayẹwo.
 
Bakan naa lo sọ pe wọn ti fi to awọn mọlẹbi oloogbe naa leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI