Yahaya Bello rọ Ọba alaye loye ni Kogi, o tun fi ẹlomiran rọpọ ẹ loju ẹsẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 8, 2024

Yahaya Bello rọ Ọba alaye loye ni Kogi, o tun fi ẹlomiran rọpọ ẹ loju ẹsẹ


Gomina Yahaya Bello ti ipinlẹ Kogi ti kede irọloye olori ọba alaye, Ohimege Igu, Konto-Nkarfe, Alaaji Abdulrazaq Isa Koto.

Bẹẹ lo tun paṣẹ pe Isa Koto ko gbọdọ duro nipinlẹ naa mọ, bi ko ṣe pe ko lọ maa gbe ni ijọba ibilẹ Rijau, ipinlẹ Niger.

Yahaya Bello yan Alaaji Salihu Akawu Seidu, tọpọ mọ si SAS lati rọpo Ohimege to rọ loye naa loju ẹsẹ, ki aaye naa ma ba a ṣofo.
Bakan naa lo kede iyansipo Alaaji Ahmẹd Tijani Anaje, to jẹ Ohi tilu Okenwen, gẹgẹ bii Ohinoyi tiluu Ebira.

Nigba to n kede idagbasoke naa ni kete ti wọn pari ipade igbimọ iṣakoso ipinlẹ naa, State Executive Committee, Bello sọ pe awọn ṣagbeyẹwo ofin ọba ati oye jijẹ daadaa, awọn si ti fi ẹnu ko si abajade.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI