Nnkan de! Wọn ji Baba arugbo ninu ijọ Ridiimu gbe lasiko to n lọ si iṣọ oru aisun ọdun l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 9, 2024

Nnkan de! Wọn ji Baba arugbo ninu ijọ Ridiimu gbe lasiko to n lọ si iṣọ oru aisun ọdun l'Ogun


Ọga ọlọpaa pata nipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu ti sọ ọ di mimọ pe baba agbalagba ẹni aadọrun ọdun ti di awati, ati pe iṣẹ ti n lọ lati ṣawari rẹ.
 
Ọjọ Iṣẹgun, Tuside, oni ni Alamutu fidi iroyin ọhun mulẹ wi pe baba naa, Adeifẹ Adelaja to jẹ ọkan lara awọn agbalagba ninu ijọ Ridiinu, Redeemed Christian Church of God (RCCG), ẹkun ti Ijẹbu Igbo di awati.
 
Alamutu ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023 to ṣẹṣẹ kọja yii ni wọn ji baba naa gbe lasiko to n lọ si iṣọ oru lati wọnu ọdun tuntun, 2024 ti a wa yii.
 
Ọga ọlọpaa naa ti wa sọ pe oun ti paṣẹ fun gbogbo ọlọpaa nipinlẹ naa lati rii daju pe wọn ko fi ọrọ baba ọhun falẹ rara, ki wọn ri daju pe wọn ṣawari ẹ, lati fa a le awọn mọlẹbi rẹ lọwọ.
 
“Mo le fi da a yin loju pe niṣe ni wọn ji baba yii gbe lasiko to n lọ si iṣọ oru aisun ọdun tuntun, ṣugbọn titi di asiko yii ni a ko tii le rii gba silẹ.
 
“Mo tun fẹ sọ fun un yin pe a ti n ba awọn mọlẹbi rẹ sọrọ, iyẹn awọn ti awọn ajinigbe ọhun n ba sọrọ
 
“Awa ọlọpaa ti n ṣiṣẹ takuntakun lati gba baba yii silẹ, a ti wa lori iṣẹ.
 
“Koda, nigba ti awọn ajinigbe ọhun n ṣi wa lọna lati mọ ibi ti wọn wa, a ṣi n gbiyanju ti wa, mo si mọ pe laipẹ a maa ṣe aṣeyọri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI