O ma ṣe o! Wọn pa gbajumọ oloye l'Ogun nipakupa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, January 9, 2024

O ma ṣe o! Wọn pa gbajumọ oloye l'Ogun nipakupa


Awọn agbebọn mẹta kan ni iroyin fi to wa leti pe wọn ti pa gbajugbaja agba oloye kan lagbegbe Itunsokun, ipinlẹ Ogun.
 
Oloye naa ti wọn pe orukọ ni Adeyinka Fọlarin ni Baaṣegun ilu Itunsokun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Nnkan bi agogo mẹjọ alẹ ni iroyin fi to wa leti pe awọn agbebọn mẹta ti wọn fura si pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ya bo ile rẹ.
 
A gbọ pe niṣe ni wọn lu Adeyinka pa, ti wọn si rii pe ẹmi ti jabọ lara rẹ ko to di pe wọn na papa bora.
 
Lara awọn ara agbegbe naa to ba akọroyin sọrọ, awọn ti bẹbẹ pe ki wọn daṣọ aṣiri bo awọn sọ pe kayeefi ni ikọlu si Oloye Adeyinka naa jẹ fun wọn.
 
 
AWIKONKO gbọ pe wọn ti sinku baba naa nilana musulumi lai fi asiko ṣofo, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu nigba to n fidi rẹ mulẹ jẹ ko di mimọ pe otitọ ni iṣẹlẹ ọhun, ati pe oun ṣẹṣẹ kuro niluu nitosi ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni.
 
Alamutu ni iṣẹ iwadii awọn ti bẹrẹ lati mọ awọn to pa Adeyinka, ki wọn si fi oju wọn ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI