O pari! Wọn ji igbakeji Giwa fasiti gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 28, 2024

O pari! Wọn ji igbakeji Giwa fasiti gbe


Ajinigbe ti ji igbakeji Giwa fasiti ipinlẹ Abia, Ọjọgbọn Uturu Godwin Emezue gbe.
 
Ọjo Ẹti, Fraide ni wọn ji ọkunrin naa gbe ninu ile-epo kan to wa ni Umuekwule, Amachara ijọba ibilẹ Umuahia South.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọjọgbọn Emezue ati iyawo rẹ ni wọno ya lati ra epo sinu mọto, asiko naa lawọn ajinigbe ọhun ya bowọn, ti wọn si wọ Ọjọgbọn sinu mọto Lexua SUV rẹ tipatipa.

A gbọ pe wọn tun gba kaadi ATM iyawo lọ.
 
Agbẹnusọ fasiti naa, Chijioke Nwogu sọ pe awọn ọlọpaa ti gbọ si iṣẹlẹ ọhun, wọn si ti bẹrẹ iwadii lati gba Ọjọgbọn Emezue jade kuro lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI