Kò sí ààyè láti pàtẹ ọjà lórí afárá Tanke- Ìjọba Kwara ṣèkìlọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 1, 2024

Kò sí ààyè láti pàtẹ ọjà lórí afárá Tanke- Ìjọba Kwara ṣèkìlọ̀


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti parọwa fun awọn araalu lati yago fun fifi afara Tanke patẹ ọja, tabi lo o lọna aitọ, eyi ti yoo mu ko tete bajẹ.

Ninu atẹjade ti igbakeji akọwe iroyin ile ijọba, Mashood, Abdulrafiu Agboola gbe jade loni, Ọjọbọ, Tọside, o sọ pe ijọba ti ṣi apa kan afara naa fun lilo araalu.

O ni ijọba gbe igbesẹ yii lati mu adinku ba sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ to n ṣẹlẹ lopopona ọhun, ati fun irọrun igbokegbodo ọkọ araalu.

Bakan naa lo sọ pe ijọba ti ṣaaju ṣi apa kan l’Ọjọru, Wẹside, pẹlu bi iṣẹ ṣi ṣe n lọ lọwọ.

Ninu atẹjade ọhun ti kọmiṣanna fọrọ akanṣe iṣẹ, Ọnarebu Abdulqowiyu Olododo buwọ lu lasiko abẹwo si afara naa, o ni afara yii ati awọn opopona ti iṣẹ ti n lọ lọwọ ti di ṣiṣi fun lilo araalu.


“Lọsan, oni, a ti ṣi apa keji afara yii fun irọrun igbokegbodo ọkọ. Awọn eeyan wa ti farada nitori pe akanṣe iṣẹ to n lọ lọwọ ye wọn.

“Ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin la kọkọ ṣi apa akọkọ afara yii, ṣugbọn loni ti a n ṣi apa keji, a fẹ ki irọrun ba araalu.

“Ohun to ku ka ṣe bayii ni ka fa ila ti yoo sọ b’awọn awakọ yoo ṣe maa rin, ati kikun awọn ẹgbẹ opopona.”

O fi kun ọrọ rẹ pe akanṣe iṣẹ naa ti de ida mọkandinlọgọrun-un lati pari.

Bẹẹ lo tun sọ pe ajọ to n ri sọrọ imọ-ẹrọ, Council for the Regulation of Engineering in Nigeria (COREN) ti fi ontẹ lu afara naa pe o dara fun lilo.

O wa rọ araalu lati ṣamulo opopona ati afara naa daadaa, lọna ti yoo jẹ ko pẹ 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI