AbdulRazaq san gbogbo gbese owo oṣu awọn Tiṣa ati oṣiṣẹ-fẹyinti ti ijọba Ahmẹd jẹ silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 5, 2024

AbdulRazaq san gbogbo gbese owo oṣu awọn Tiṣa ati oṣiṣẹ-fẹyinti ti ijọba Ahmẹd jẹ silẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti kede sita wi pe oun ti san gbogbo gbese ajẹẹlẹ owo oṣu awọn Tiṣa ati awọn oṣiṣẹ-fẹyinti.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, owo awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, awọn olukọ ati awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ti Gomina Abdufatah Ahmẹd jẹ ko too kuro nijọba ni Gomina AbdulRazaq san.
 
Biliọnu kan naira le diẹ ni owo ti gomina san.

Ṣaaju ni AbdulRazaq ti sọ pe gbogbo gbese ti iṣakoso ana jẹ silẹ loun yoo san koun too gbe ijọba silẹ.

Bakan naa, ninu oṣu kinni, ijọba bẹrẹ sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ eto ilera labẹ aburada CONHESS ni ijọba ibilẹ.

Bẹẹ ni ijọba tun san owo iranwọ ẹgbẹrun mẹwaa naira fun awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹ fẹyinti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI