Ijọba gbe atunṣe otẹẹli Kwara fun ileeṣẹ Crystal Group ti Mashood Mustapha - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 7, 2024

Ijọba gbe atunṣe otẹẹli Kwara fun ileeṣẹ Crystal Group ti Mashood Mustapha


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe akanṣe iṣẹ atunṣe otẹẹli Kwara fun ileeṣẹ Crystal Group to jẹ ti Ọnarebu Mashood Mustapha.

Ninu lẹta ti wọn bu ọwọ lu lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni, ọdun yii, ni ijọba ti sọ pe ki ileeṣẹ Crystal Group pẹlu biliọnu mẹta mẹta naira ti wọn ti pese nilẹ fun atunṣe naa.

Ijọba ni biliọnu mẹta naira ni eto to wa nilẹ gẹgẹ bii Government’s Bill of Quantities (BOQ).

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni Ọnarebu Mustapha kọ lẹta kan, nibi to ti fẹsun kan Gomina Abdulrahman Abdulrazaq wi pe o n na owo ilu ninakuna.
 
Mustapha sọ pe ileeṣẹ Crystal Group oun le ṣe akanṣe iṣẹ naa pẹlu biliọnu mẹta naira pẹlu awọn ohun ti ijọba n fẹ.

Ninu lẹta ti adajọ agba ipinlẹ naa to tun jẹ kọmiṣanna fọrọ eto idajọ, Senior Ibrahim Sulyman kọ, lo ti sọ pe ki Mashood Mustapha wa gba akanṣe iṣẹ ọhun, to ba ti le ṣe awọn nnkan ti ijọba n fẹ.
 
Bakan naa ni ijọba tun fun ileeṣẹ Crystal Group ni gbedeke lati fi dahun lẹta naa titi oni ọjọ keje, oṣu keji, ọdun  2024.
 
Aarin oṣu mẹrinlelogun ni ileeṣẹ naa yoo fi ṣatunṣe otẹẹli Kwara, ti anfaani yoo si tun wa fun lati lo o fun ọdun mẹẹdogun ko too gbe silẹ pada fun ijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI