Ayajọ ololufẹ: Ileeṣẹ Adron Homes fifẹ han s'awọn araalu, wọn ja owo ilẹ ati dukia wọn silẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 7, 2024

Ayajọ ololufẹ: Ileeṣẹ Adron Homes fifẹ han s'awọn araalu, wọn ja owo ilẹ ati dukia wọn silẹ


Ileeṣẹ Adron Home and Properties Limited ti kede ẹdinwo lori iye ti wọn n ta awọn ilẹ ati dukia wọn lojuna lati fi ifẹ aiṣẹtan han si gbogbo awọn onibara wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, gbogbo ọjọ kẹrinla, oṣu keji ọdọọdun ni ayajọ ololufẹ kaakiri agbaye, nibi ti awọn eeyan ti maa n fi ifẹ han si ara wọn loriṣiriṣi ọna.
 
Ileeṣẹ Adron Homes to n lewaju ninu awọn ileeṣẹ to n ṣowo dukia lorileede Naijiria ti wa darapọ lati fi ifẹ han si gbogbo awọn onibara wọn kaakiri agbaye.
 
Wọn ti fi ẹdinwo si gbogbo ilẹ ati dukia wọn lati le jẹ ki wọn jẹ anfaani nla lati di onilẹ ati onile lori.

Awọn onibara tẹlẹ ati awọn onibara tuntun ni anfaani yii wa fun, gẹgẹ bi awọn alakoso ileeṣẹ Adron Homes ṣe ṣalaye ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ si AWIKONKO.
 
Nibi ti anfaani yii tun rọrun de, awọn eeyan tun le ra ilẹ tabi dukia lati fi ṣe ẹbun fun awọn ololufẹ wọn nibikibi ti wọn ba wa.

Kaakiri ipinlẹ bii Ekoo, Ogun, Ọṣun, Ọyọ, Ekiti, Niger, Abuja, Nasarawa, Jos, ati awọn miran ni ileeṣẹ Adron Homes ni ilẹ ati dukia si, ti awọn eeyan si ti n gbe ibẹ.

Ma ṣe jafara, ma si ṣe fi asiko ṣofo lati darapọ mọ anfaani ara-ọtọ yii.
 

Ẹ le kan si awọnn alakoso ileeṣẹ Adron Homes lori awọn ikanni ayelujara wọon fun alaye lẹkunrẹrẹ tabi ibeere.
 
Facebook (Adronhomesofficial), 
Twitter (@adronhomes), 
Instagram (@adronhomesofficial).
 
Bakan naa lẹ tun lọ si ikanni ayelujara wọn www.adronhomesproperties.com 
 
Ayika to dara, to dun un wo loju pẹlu awọn ohun amayedẹrun, to fi mọ eto aabo to pe ye lo wa ni gbogbo ibi ti Adron Homes ni ilẹ ati dukia si kaakiri Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI