Ijọba Kwara ro ẹgbẹrun mẹjọ ọdọ ati awọn obinrin lagbara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 7, 2024

Ijọba Kwara ro ẹgbẹrun mẹjọ ọdọ ati awọn obinrin lagbara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ si san owo iranwọ fun ẹgbẹrun mẹjọ ọdọ ati awọn obinrin kaakiri ipinlẹ naa.
 
Ikede yii lo waye ninu atẹjade ti alakoso agba fun Kwara State Social Investment Programmes (KWASSIP), Ọmọwe Abdulwasiu Olayinka Tejidini gbe jade lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Tejidini sọ pe ọjọ naa ni pinpin owo ọhun yoo bẹrẹ kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara.

“Ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin, awọn ikọ amuṣẹya wa ti lọ kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara lati ṣagbeyẹwo awọn ti owo ọhun yoo tọ si.
 
“Agbekalẹ yii jẹ awọn eto iranwọ ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq dawọ le lati mu awọn araalu kuro ninu iṣẹ ati oṣi lawujọ.

“Ẹni kọọkan yoo bẹrẹ sii gba ẹgbẹrun marundinlọgbọn owo naira lati mu igbayegbadun ba wọn.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI