Ẹẹmẹta laarin ọsẹ lawọn oṣiṣẹ ijọba yoo maa lọ si ibi-iṣẹ - Sanwo-Olu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 22, 2024

Ẹẹmẹta laarin ọsẹ lawọn oṣiṣẹ ijọba yoo maa lọ si ibi-iṣẹ - Sanwo-Olu


Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Ekoo ti kede pe igba mẹta ni awọn oṣiṣẹ ijọba yoo maa lọ si ibi-iṣẹ.

Oni, Ọjọbọ, Tọside ni Gomina Sanwo-Olu kede sita nigba to n kọminu ipo ti eto ọrọ aje orileede Naijiria wa.

Nibi ipade awọn oniroyin naa ni gomina ti sọ pe awọn oṣiṣẹ lati ipele kini titi de ipele kọkanla yoo maa lọ si ibiṣẹ ni igba mẹta laarin ọsẹ lojuna lati wa iyanju si ipenija eto ọrọ aje.

O tẹsiwaju pe awọn oṣiṣẹ lati ipele kẹẹdogun si ipele ikẹtadinlogun yoo maa lọ si ibi-iṣẹ ni igba mẹrin laarin ọsẹ, bẹrẹ lati ọsẹ yo n bọ.

Bẹẹ lọ fi kun un pe awọn olukọ yoo maa lọ si ibi-iṣẹ ni igba marun-un lọsẹ nitori ipo ti eto ẹkọ wa.

Sanwo-Olu tun jẹ ko di mimọ pe awọn yoo ja owo ọkọ wa silẹ ni ida mẹẹdọgbọn ti awọn eeyan n wọ ọ, bakan naa ni wọn yoo tun ni ajọsọ pẹlu ẹgbẹ awọn awakọ, bẹrẹ lati opin ọsẹ yii.

Bẹẹ lo ni awọn yoo ṣawari awọn ile ounjẹ kaakiri ijọba ibilẹ lati maa bọ, o kere tan ẹgbẹrun kan eeyan lojumọ.

O fi kun un pe awọn yoo ṣi awọn ọja mejilelogoji ni gbogbo ọjọ Aje, nibi ti awọn araalu yoo ti maa lọ ra eroja ounjẹ ni ida meedogun si iye ti wọn n ta a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI