AbdulRazaq kẹdun iku Alaaja Dupẹ Belgore - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 25, 2024

AbdulRazaq kẹdun iku Alaaja Dupẹ Belgore


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ ti idile Oloogbe Alaaja Dupẹ Belgore to jẹ iyawo Jarma tiluu Ilọrin, Alaaji Kọla Belgore.

AbdulRazaq nigba to n ṣapejuwe oloogbe naa, o ni lara awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn fi ara wọn jin fun iṣẹ ilu ni Alaaja Belgore jẹ nigba to wa lẹnu iṣẹ.

O ni ọkan pataki lara awọn igi lẹyin ọgba fun mọlẹbi ati olori agbegbe ti kii fi igba kan bo ọkan ninu ni.

Bo ṣe n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere, naa lo tun gbadura pe ki Ẹlẹdaa mu awọn mọlẹbi rẹ lọkan le lasiko ipadanu nla yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI