Minisita gbe oṣuba kare fun gomina Kwara lori iforukọsilẹ awọn fun eto 3MTT - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 27, 2024

Minisita gbe oṣuba kare fun gomina Kwara lori iforukọsilẹ awọn fun eto 3MTT


Minisita f'ọrọ eto ikansira-ẹni lorileede Naijiria, Ọmọwe Bọsun Tijani ti gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori bi awọn ọdọ ipinlẹ Kwara ṣe iforukọ silẹ fun akanṣe eto 3 Million Technical Talent (3MTT).

Ọmọwe Tijani lo sọrọ naa loju opo 'X' rẹ laipẹ yii, nibi to ti sọ pe iwuri nla lo jẹ.

Ninu ọrọ to kọ naa, o ni
"Ipinlẹ miran to tun n tẹsiwaju. Ẹnṣeun bi ẹ ko ṣe jẹ ki awọn eeyan wa ni Kwara gbẹyin.

"Gomina AbdulRazaq ti bẹrẹ si sọ ipinlẹ naa di ti onigbalode, ko si ya mi lẹnu."

Ọmọwe Tijani fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ takuntakun ti gomina naa n ṣe lo jẹ ki awọn ọdọ ipinlẹ naa ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ogoji fi orukọ silẹ fun eto 3MTT.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI