Lati le jẹ ki iṣẹ eto aabo araalu tubọ fi ẹsẹ mulẹ ju ti tẹlẹ lọ, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fi ọpọlọpọ ọkada alupupu tuntun ta ileeṣẹ ologun lọrẹ.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni ijọba Kwara gbe igbesẹ naa lati le jẹ ki ẹmi ati dukia araalu wa labẹ aabo to pe ye.
Gẹgẹ bi ijọba Kwara ṣe ṣalaye, wọn ni awọn ọkada tuntun wọnyii duro gẹgẹ bii irinṣẹ ti awọn ẹṣọ ologun yoo lo lati koju awọn agbebọn aṣekupani ti wọn n gba inu igbo wọ ipinlẹ naa lati ṣiṣẹ buruku.
Gomina AbdulRazaq wa lara awọn gomina Naijiria ti wọn ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ eto aabo.
Yatọ si eyi, ijọba Kwara ti figba kan ta awọn ileeṣẹ eleto aabo kaakiri ipinlẹ naa lọrẹ mọto ti yoo mu iṣẹ ya.
Ọlayinka Fafoluyi to jẹ amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ iroyin ayelujara, ẹni to fi atẹjade ranṣẹ si wa jẹ ko di mimọ pe eto aabo ẹmi ati dukia araalu jẹ gomina logun pupọ.
No comments:
Post a Comment