Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ iku gbajugbaja oniṣowo nla kan niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo ṣi n jẹ fun awọn eeyan, paapaa awọn to sunmọ ọn.
Gbajugbaja oniṣowo ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Ṣẹsan Adelabu ni wọn lo ni ile-epo Emirate to gbajumọ niluu Akurẹ.
A gbọ pe niṣe ni Adelabu ṣa iyawo pa, ko to di pe oun naa lọ gba ẹmi ara rẹ.
Oogun apẹfọn ti a mọ si Insecticide ni wọn sọ pe Adelabu da mu lati fi gba ẹmi ara rẹ lalẹ ọjọ Ẹti, Fraide, ọsẹ yii lagbegbe Alagbaka niluu Akurẹ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe wọn ti gbe oku Adelabu ati iyawo rẹ lọ si mọṣuari.
Nigba to n sọrọ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmi Ọdunlami sọ pe otitọ ni, ati pe iṣẹ iwadii awọn ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iku awọn mejeeji.
No comments:
Post a Comment