O pari! Iyawo Emefiele, tọkọ-taya wọ wahala lori ẹsun jibiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 10, 2024

O pari! Iyawo Emefiele, tọkọ-taya wọ wahala lori ẹsun jibiti


Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati jibiti lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti kede iyawo gomina banki ilẹ wa tẹlẹ, Margaret Emefiele gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan ọkọ rẹ, Godwin Emefiele.

EFCC kede Margaret Emefiele; Anita Omoile ati ọkọ rẹ, Jonathan Omoile, pẹlu Eric Odoh loju opo ayelujara wọn lalẹ ọjọ Ẹti, ọsẹ yii.

Wọn ni awọn eeyan naa lọwọ si iwa jibiti owo to jẹ ti ijọba Naijiria, ki wọn si wa sọ ibi ti awọn owo naa wa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ẹsun biliọnu meji din ni igba (₦1.8b) naira ati miliọnu mẹfa le diẹ ($6.2m) owo dọla ni wọn fi kan gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ naa.

Wọnyi ni ohun ti EFCC gbe jade nipa awọn ti wọn n wa naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI