Ọkada ni Babatunde ati Taiwo jigbe l’Ogun ki ọwọ too tẹ wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 10, 2024

Ọkada ni Babatunde ati Taiwo jigbe l’Ogun ki ọwọ too tẹ wọn


Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun, Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, ti a mọ si codenamed So-Safe Corps ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi adigunjale meji kan lori ẹsun ọkada ti wọn jigbe.

Ọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun ti a wa yii ni a gbọ pe awọn mejeeji ji ọkada kan to jẹ ti Odugbayi Qudus gbe.

Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ileeṣẹ So Safe, Mọruf Yusuf ṣe sọ, o ni nnkan bi aago kan aabọ aarọ ni Babatunde Azeez, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Avose Taiwo toun jẹ ẹni ọgbọn ọdun ji ọkada naa gbe.

O fi ye wa pe nnkan bi aago mẹfa aabọ aarọ lọwọ tẹ awọn mejeeji.

Nigba to sọ pe wọn jẹwọ, Yusuf sọ pe niṣe mẹkaniiki kan to n jẹ Ahotin to n gbe ni Mogbara, Okere-Ilaṣhẹ niluu Ipokia lo ra ọkada ọhun ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira lọwọ awọn.

O ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun ni mẹkaniiki naa ṣi san fun wọn, ṣugbọn ti awọn ko tii ri owo to ku gba lọwọ ẹ.

Yusuf ni titi di asiko ti oun gbe iroyin yii si wa leti ni awọn ko tii rọwọ to mẹkaniiki naa, ẹni to sọ pe o ti na papa bora.

O wa jẹ ko di mimọ pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki iṣẹ iwadii tubọ bẹrẹ lẹkunrẹrẹ, ati pe ki wọn ṣi lọ fa awọn mejeeji yii le awọn ọlọpaa ẹkun Ipokia lọwọ.

Bakan naa lo fi ye wa pe awọn ri aga ijokoo ọkada naa ati ẹgbẹrun lọna ogoji naira gba lọwọ awọn mejeeji, eyi to jẹ gẹgẹ bi ẹri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI