Wọn ju gbajumọ oniṣowo sẹwọn ọdun kan lori jibiti miliọnu mẹta aabọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 15, 2024

Wọn ju gbajumọ oniṣowo sẹwọn ọdun kan lori jibiti miliọnu mẹta aabọ


Onidajọ Abdulhamid Yakubu ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Gombe ti ju ọunrinkan, Isiyaku Dahiru sẹwọn o'su mejila lori ẹsun lilu jibiti owo ti ko din ni miliọnu mẹta aabọ {N3.5m} naira.
 
Dahiru ati ileeṣẹ rẹ, Zafran and Brothers Investment Limited ni ile-ẹjọ ju sẹwọn papọ.
 
Ẹsun kan ṣoṣo to nii ṣe pẹlu jibiti ni ajọ to n gbogunti iwa jibiti ati ajẹbanu, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC fi kan Dahiru.
 
Ẹnikan ti wọn pe ni Usman Ahmad ni Dahiru gba owo naa lọwọ ẹ, pẹlu ẹtanjẹ wi pe oun yoo ba a ra baagi iyọ ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin iyọ to jẹ aadọta kilogiraamu.
 
Niṣe ni Dahiru gba owo naa, to si lo owo ọhun fun bukata ara rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI