Ajọ NAFDAC ti ileeṣẹ omi meji pa l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 14, 2024

Ajọ NAFDAC ti ileeṣẹ omi meji pa l'Ogun


Ajọ to n ṣabojuto ohun jijẹ ati mimu pẹlu lilo oogun lorileede Najiria, National Agency For Food And Drug Administration and Control, NAFDAC, ti ti ileeṣẹ omi ti ko din ni meji pa nipinlẹ Ogun.
 
Wọn ni awọn ileeṣẹ naa ko ni iwe aṣẹ iforukọsilẹ ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ, eyi ti wọn sọ pe akoba nla ni yoo jẹ fun araalu.
 
Ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta ni awọn ileeṣẹ meji ọhun wa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Nigba to n sọrọ, alakoso ajọ naa nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Philip Benu ṣalaye pe awọn ileeṣẹ omi meji yii ko ni iwe aṣẹ, ati pẹ wọn ko ni awọn amuyẹ ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ.
 
Benu ni lẹyin ayẹwo ti ẹkun toun ti jẹ alakoso ṣe, awọn ṣakiyesi pe ọna eru ni wọn gba bẹrẹ iṣẹ.
 
Siwaju sii lo ni awọn ti pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa lati yọju si wọn, ki wọn si wa sọ tẹnu wọn ko to di pe awọn mọ igbesẹ to kan.
 
O tiẹ jẹ ko di mimọ pe nigba ti awọn kọkọ lọ ṣayẹwo si awọn ileeṣẹ naa, wọn ko ba oṣiṣẹ kankan lati fọrọ wa lẹnu wo, to si ni awọn ti awọn ileeṣẹ naa pa, pẹlu iwe ipe ti wọn kọ silẹ fun wọn.
 
O fi kun ọrọ rẹ pe ko si ẹnikẹni to yọju si wọn lati wa sọ tẹnu wọn, to si lo jẹ kayeefi pe niṣe ni awọn ileeṣẹ naa tun n ba iṣẹ wọn lọ pẹlu ayederu nọnba awọn, eyi to ni wọn fi n lu awọn araalu ni jibiti.
 
Bẹẹ lo ni ọpọ awọn eeyan lo wa to jẹ pe ayederu iwe aṣẹ ni wọn n lo lati maa lu awọn araalu ni jibiti, ati pe awọn yoo fi kele ofin gbe wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI