Iṣẹ akanṣe nla miran n bọ lọna ni Kwara - Gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 13, 2024

Iṣẹ akanṣe nla miran n bọ lọna ni Kwara - Gomina


Ileri tuntun ti gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tun ṣe fun araalu bayii ni pe oun ti pari ajọsọ pẹlu ijọba apapọ lati ṣe opopona tuntun si ipinlẹ naa.

Gomina sọ pe owo iyebiye to le ni biliọnu naira ni wọn yoo fi ṣe opopona tuntun yii, fun igbadun araalu.

Ninu ọrọ ti gomina gbe jade laipẹ yii, o ni oun pẹlu Gomina Ahmẹd Usman Ododo lawọn jọ ṣabẹwo si minisita f'ọrọ iṣẹ ode, Onimọ-ẹrọ David Umahi.

AbdulRazaq ni lẹyin toun pẹlu Aarẹ sọrọ tan loun lọ ba Umahi sọrọ lori ṣiṣe opopona Ilọrin si Lọkọja mọ Omu Aran si Kabba.

Bakan naa lo ni oun rọ minisita f'ọrọ iṣẹ ode lori ṣiṣe afara Oko-Olowo ati Shao, fun irọrun araalu.

AbdulRazaq ni o di dandan lati lọ bẹ ijọba apapọ lori awọn opopona wọnyi lati le doola ẹmi ati dukia araalu.

Bẹẹ lo sọ pe oun nigbagbọ ati idaniloju pe iṣẹ yoo bẹrẹ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI