Aṣọ ni Gbenga jigbe l'Ado Ekiti, ki adajọ to ju sẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 25, 2024

Aṣọ ni Gbenga jigbe l'Ado Ekiti, ki adajọ to ju sẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara


Onidajọ Baknọle Oluwasanmi ti ile-ẹjọ  Majisireeti to wa niluu Ado Ekiti, ipinlẹ Ekiti ti ju gendekunrin, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn kan, Olu Gbenga sẹwọn oṣu mẹrin pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta ni Onidajọ Oluwasanmi ju Gbenga sẹwọn naa lori ẹsun ole jija.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ẹnikan to n jẹ Babatunde Bagilaje lo sa asọ jakẹẹti naa sori ikọ, ko to di pe Gbenga lọ jii ka ni nnkan bi agogo mẹrin irọlẹ.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Bus Terminal to wa ni garaaji atijọ, Ado Ekiti ni wọn sọ pe Gbenga n gbe, nibi si lo ti ji aṣọ ọhun ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira.
 
Ẹsun naa ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 302 ninu iwe ọdaran ti ipinlẹ Ekiti, ọdun 2021, to si ni ijiya ninu.
 
Bi wọn ṣe ka ẹsun naa si Gbenga lọrun, lo ti sare sọ pe oun jẹbi lai ni alaye kankan, ati pe ki wọn boju aanu wo oun.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Oluwasanmi Bankọle sọ pe ẹri toun ri gba fi aridaju han pe ole ni Gbenga n ja, fun idi eyi, o gbọdọ foju winna ofin.
 
O wa paṣẹ pe ki gbenga lọ lo oṣu mẹrin gbako lọgba ẹwọn ijọba apapọ to wa niluu Ado Ekiti, bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta, ọdun 2024.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI