Ẹ dẹkun igi gige ninu igbo lọna aitọ, ijọba Kwara kilọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 25, 2024

Ẹ dẹkun igi gige ninu igbo lọna aitọ, ijọba Kwara kilọ



Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣe ikilọ fun gbogbo awọn to n ge igi ninu igbo lọna aitọ lai gba aṣẹ ijọba.
 
Bakan naa ni ijọba tun pe fun ajọṣepọ awọn araalu, paapaa awọn ileeṣẹ aladani lori ọna lati dẹkun gige igi ninu igbo lọna aitọ, paapaa lai gbin awọn miran pada, eyi ti wọn pe ni Deforestation.

Igbakeji gomina, Kayọde Alabi to ṣoju gomina nibi akanṣe eto ọlọdọọdun 2024 International Day of Forest, eyi to waye gbọngan Flower Garden tiluu Ilọrin.

Nigba to n sọrọ, o ni o ṣe pataki fun ajọṣepọ ati ifọwọsowọpọ to lọọrin pẹlu awọn eeyan, paapaa awọn ileeṣẹ aladani lori ọna lati daabo bo awọn igbo ọba nibi ti awọn kan ti lọ n ge igi.
 
Nibẹ lo ti ni lati dẹkun iwa yii, awọn nilo iranlọwọ araalu nipa ọgbọn ati imọ araalu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI