Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria lo ni ẹgbẹ oṣelu Labour - Awọn alakoso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 21, 2024

Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria lo ni ẹgbẹ oṣelu Labour - Awọn alakoso


Igbakeji alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, Ayọ Ọlọrunfẹmi ti sọ pe ẹgbẹ awọn lo ni ẹgbẹ oṣelu Labour, kii ṣe awọn oloṣelu.
 
Ọlọrunfẹmi lo sọ eyi lasiko to n dahun awọn ibeere lori eto kan nileeṣẹ amohunmaworan Arise l'Ọjọru, ọsẹ yii.
 
Eyi lo si waye lẹyin iwọde ifẹhonuhan ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ NLC ṣe lati takoipade gbogboogbo ti ẹgbẹ oṣelu Labour fẹẹ ṣe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta ti a wa yii.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
“Awọn oṣiṣẹ orileede Naijiria lo ni ẹgbẹ oṣelu Labour, kii ṣe NLC, ati pe bi a ba tete mọ eyi, yoo dara. A ni TUC, a ni NLC, bẹẹ la tun ni awọn ẹgbẹ nla-nla miran.
 
“A tun ni awọn miran lori eto ọrọ aje, awọn ti wọnj kii ṣe ẹgbẹ rara, gbogbo wọn ni wọn ni ẹgbẹ oṣelu Pabour.
 
“Fun NLC lati fẹẹ sọ pe awọn nikan lawọn ni ẹgbẹ Labour, ofuutufẹẹtẹ lasan ni. NLC ko le maa sọ pe awọn lo ni ẹgbẹ Labour.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI