Ọjọgbọn Adaramaja di alakoso ẹgbẹ awọn alaga SUBEB ni Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 25, 2024

Ọjọgbọn Adaramaja di alakoso ẹgbẹ awọn alaga SUBEB ni NaijiriaAlaga ẹgbẹ ajọ to n ri sọrọ eto ẹkọ, iyẹn State Universal Basic Education Board, SUBEB nipinlẹ Kwara, Ọjọgbọn Shehu Raheem Adaramaja ti di alakoso (Dean) ẹgbẹ awọn alaga ajọ naa lorileede Naijiria.
 
Ọmọwe Hamid Bobboyii to jẹ akọwe agba fẹgbẹ naa lo kede sita laipẹ yii nibi ipade oloṣooṣu wọn to waye niluu Abuja.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ameenat Abiọla buwọ lu, eyi ti ẹda rẹ tẹ awọn akọroyin lọwọ lo ti niipa takuntakun ti Ọjọgbọn Adaramaja ko ninu ajọ ọhun lo mu ki wọn yan an gẹgẹ bi alakoso agba.

Bobboyii ni Adaramaja ti ko ipa ribiribi ti ko ṣee gboju fo, to si ni awọn tun nilo rẹ lati mu ajọ ọhun tẹsiwaju, lo mu ki wọn yan an gẹgẹ bi olori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI