O ma ṣe o! Ijamba ọkọ ofurufu gba ẹmi eeyan marun-un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 5, 2024

O ma ṣe o! Ijamba ọkọ ofurufu gba ẹmi eeyan marun-un


Ko din ni eeyan marun-un ti wọn tun ti ta teru nipa lonii, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun, oṣu kẹta, ọdun 2024 nigba ti wọn sọ pe ọkọ baluu kekere kan ja lulẹ lori iṣẹ.

Agbegbe kan ti wọn pe ni Nashville ni wọn ni ijamba ọhun ti waye, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe lọ lori ikanni ayelujara 'X' wọn.
 
Wọn jẹ ko di mimọ pe ọkọ baluu naa ti kọja agbegbe Charlotte Pike, ko to di pe o jabọ lulẹ.
 
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ ibi ti ọkọ baluu kekere yii ti n bọ, ati ibi to n lọ.
  
AWIKONKO gbọ pe awọn alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ irin ajo inu  afẹfẹ, Federal Aviation Administration wa nibi ijamba ọhun, ko to di pe ajọ to n ri sọrọ aabo popona, National Transport Safety Board yoo debẹ lati mọ bi nnkan ṣe n lọ.
 

Awọn alakoso papakọ ofurufu Nashville’s John Tune ni a gbọ pe wọn ti gba iroyin ni nnkan bi agogo mẹjọ ku ogun iṣẹju, alẹ ọjọ Aje to kọja wi pe baluu kekere kan ni ipenija, to si n wa ibi ti yoo balẹ si, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe ṣalaye siwaju sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI