Ọbasanjọ ni ki ijọba Naijiria lọ gba amọran lori eto ọrọ aje to dorikodo ni Zimbabwe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 5, 2024

Ọbasanjọ ni ki ijọba Naijiria lọ gba amọran lori eto ọrọ aje to dorikodo ni Zimbabwe


Aarẹ tẹlẹri Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti gba ijọba orileede yii lamọran lati lọ gba amọran lorileede Zimbabwe lori bi wọn ṣe moribọ kuro ninu ọwọngogo.
 
Ọbasanjọ ni ki awọn alakoso Naijiria lasiko yii lọ si Zimbabwe lati lọ wa ọna abayọ si iṣoro to n dojukọ wọn, eyi to ti dojukọ orileede naa tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ti moribọ bayii.

Aarẹ tẹlẹ naa lo sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii nibi akanṣe eto awọn ọdọ, iyẹn Youth Leadership Symposium to waye lara awọn eto ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtadinlaadọrun (87years) rẹ.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ki orileede Naijiria kẹkọọ lara Zimbabwe ti awọn naa ti ni iru ipenija yii ri nigba kan, ti wọn si ti gun oke agba.
 
Bakan naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria lati mu ọkan le lasiko ipenija yii, to si ni awọn alakikanju ni lati tẹsiwaju ninu rogbodiyan.
 
Siwaju sii lo tun rọ awọn araalu lati gbe iṣoro ati ipenija naa si ọwọ Ọlọrun, pẹlu bo ṣe ni fun igba diẹ ni ebi ati iya to n pa araalu, kii ṣe titi lai.
 
“Nigba ti asiko naa ba ruju, to si le koko, awọn alakikanju maa n tẹsiwaju ni...Ko si iṣoro to jẹ tuntun, ko si nii si iṣoro ti yoo jẹ titi lai.
 
“Gbigba ẹmi ara ẹni kii ṣe opin si iṣoro yoowu, koju rẹ, ki o si gbe lọ siwaju Ọlọrun, nitori pe Oun lo le ṣe ohun gbogbo.
 
“Nigba ti ẹ ba ni iṣoro, ẹ wo awọn to ti ni iru iṣoro yii tẹlẹ, ati bi wọn ṣe la a kọja.
 
“A ni iṣoro to n mu ki eto ọrọ aje maa lọ soke-silẹ, ṣugbọn a ti ni orileede ti awọn naa ni iri iṣoro yii ri. Bẹẹni, a ni, Zimbabwe ni iru rẹ laipẹ yii.
 
“Ki lo de ti a ko le lọ ba wọn, koda bo jẹ ọna miran ni awa yoo gbe ti wa gba. Koda, bi ọna ti a wa fẹẹ gbe ti wa gba ba maa yatọ, ki lo de ti a ko le lọ ba wọn, ka si beere bi wọn ṣe yanju iṣoro ti wọn?

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI