Ṣeun Ọdunlami di akapo owo fẹgbẹ akọroyin l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 25, 2024

Ṣeun Ọdunlami di akapo owo fẹgbẹ akọroyin l'OgunGbajugbaja akọroyin nni, Oluwaṣeun Ọdunlami ni wọn ti dibo yan gẹgẹ bi akapo owo fun ẹgbẹ awọn to n gbe iwe iroyin jade, eyi ti a mọ si Federated Chapel nipinlẹ Ogun.

Ọṣe to kọja yii la gbọ pe Ṣeun Ọdunlami jawe olubori nibi eto idibo to waye ni gbọngan awọn akọroyin to wa lagbegbe Oke-Ilewo niluu Abẹokuta.
 
Ṣeun to jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ awọn akọroyin to n tọpinpin lorileede Naijiria, Nigeria Guild of Investigative Journalism (NGIJ) ni wọn yan nibi eto idibo abẹle to waye.
 
Ọjọbọ tii ṣe Tọside, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹta ni eto idibo ọhun waye, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Akọwe ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Bunmi Adigun lo ṣakoso eto idibo ọhun nibi ti wọn ti yan awọn mẹta nibi eto idibo abẹle ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI