Nitori ki n le jogun dukia iyawo mi ni mo ṣe fẹẹ fi majele pa danu - Ibrahim jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 25, 2024

Nitori ki n le jogun dukia iyawo mi ni mo ṣe fẹẹ fi majele pa danu - Ibrahim jẹwọ


Baale ile,ẹni ogoji ọdun ti ẹ n wo yii, Bahu Ibrahim ti sọ pe nitori ki oun ba a le jogun gbogbo ohun ini iyawo oun, loun ṣe mọ-ọn-mọ fẹẹ fi majele pa a danu lai mọ pe aṣiri maa pada tu sita.
 
Ibrahim lo jẹwọ iwa buruku to hu nigba ti awọn ọlọpaa n fọrọ wa a lẹnu wo, lẹyin ti aṣiri rẹ tu si wọn lọwọ.
 
Abule kan ti wọn n pe ni Danadama, eyi to wa nijọba ibilẹ Sule Tankarkar, ipinlẹ Jigawa niṣẹlẹ ọhun ti waye lọsẹ to kọja yii.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, a gbọ pe niṣe ni Ibrahim fi majele sinu ọti ati ẹran to gbe fun iyawo rẹ, Zakiya Uzairu lati jẹ, pẹlu erongba wi pe kiyẹn le gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Ọga ọlọpaa pata nipinlẹ naa, A T. Abdullahi, nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, o ni ẹni ọdun marundinlogoji ni Zakiya ki ọkọ rẹ too ran an lọ sọrun aremabọ.
 
Abdullahi ni Ibrahim ko ni erongba meji to fi ṣeku pa iyawo rẹ yii, bi ko ṣe lati jẹ ki gbogbo ogun tiyẹn ni jẹ toun nikan.
 
O ni bi iroyin ọhun ṣe tẹ wọn lọwọ, lawọn ti tete dide lati gbera lọ sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si gbe Ibrahim lọ si agọ ọlọpaa to wa Sule Tankarkar lati fọrọ wa a lẹnu wo.
 
O sọ pe ibẹ ni funra Ibrahim lo jẹwọ ara rẹ, to si tun n bẹbẹ fun idariji.
 
Lara awọn dukia ti Ibrahim loun fẹẹ jogun naa ni Ewurẹ, Aguntan, ati awọn Maluu to sọ pe iyawo ni to pọ.
 
Ọga ọlọpaa naa ni bi ko ba ṣe ori to ko obinrin naa yọ ni, to si tete gboorun pe majele wa ninu ohun ti Ibrahim gbe foun, ki ba ti gba ọrun alakeji lọ.
 
O sọ pe obinrin naa lo ta awọn ọlọpaa lolobo, ti wọn fi lọ gbe e.
 
Bẹẹ lo sọ pe Ibrahim yoo foju ba ile-ẹjọ lati ṣalaye ara rẹ niwaju adajọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI