AbdulRazaq ba adajọ agba Kwara kẹdun lori iku baba rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 4, 2024

AbdulRazaq ba adajọ agba Kwara kẹdun lori iku baba rẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ si adajọ agba nipinlẹ Kwara, Onidajọ Abiọdun Ayọdele Adebara ati mọlẹbi lori iku baba rẹ, Alagba Adebara Adio Durodoye Dogo.

Ninu lẹta ibanikẹdun naa ni gomina ti ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ẹni to gba iyi lawujọ nipa iwa akikanju, adari ati ipa rere to ti ko lawujọ fun idagbasoke ati ilọsiwaju.

O ni ipa ti ologbe naa ko nigba aye rẹ, ko ṣee gbagbe, ati pe awọn iwe rere naa farahan ninu igbesi aye awọn ọmọ.
 
Nigba to n gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa to jade laye lẹni ọdun mejidinlọgọrun naa si afẹfẹ rere, bẹẹ lo gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn mọlẹbi ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI