Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristẹẹni, CAN fi oye Ọtun Aṣiwaju Onigbagbọ da alaṣẹ Adron Homes lọla (Fọto) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 4, 2024

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristẹẹni, CAN fi oye Ọtun Aṣiwaju Onigbagbọ da alaṣẹ Adron Homes lọla (Fọto)


Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kritiẹni ti a mọ si Christian Association of Nigeria, CAN ti sọ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing gẹgẹ bi Ọtun Aṣiwaju Onigbagbọ tilẹ Rẹmọ ati iyawo rẹ, Yeye Aderonkẹ EmmanuelKing gẹgẹ bi Yeye Ọtun Aṣiwaju Onigbagbọ tilẹ Rẹmọ.

Inu ijọ Communion Faith Assembly, Garden of Faith, to wa lagbegbe Kemta Housing Estate, Idi-Aba niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni eto ọhun ti waye.
 
Awọn agbaagba ẹgbẹ naa ti Biṣọọbu Tunde Akin-Akinsanya jẹ olori wọn ni wọn fontẹ lu Aarẹ EmmanuelKing ati iyawo rẹ.
 
Lara awọn to wa nibẹ ni alaga CCN, Rev Dr O Oyeniyi; alaga CSN, Most Rev Dr Peter Odetoyinbo; alaga ECWA/TEKAN, Rev Dr S.O Babayomi; Pastor J K Onakoya (JP), alaga CPFN/PFN, ati Rev Leke Sopein, alaga OAIC.

Ọkan pataki ni Aarẹ Adetọla EmmanuelKing ninu ẹgbẹ CAN, ẹka tipinlẹ Bayelsa nigba to lọ ṣe agunbanirọ rẹ nibẹ, ti wọn si lo ko ipa ribiribi manigbagbe.
 
Aarẹ Adetọla ni alakoso ẹgbẹ Nigeria Christian Corpers’ Fellowship (NCCF) ni Bayelsa laarin ọdun 2000 si 2001.
 
Bakan naa lo tun jẹ Aarẹ ẹgbẹ Youth Fellowship of Living Faith Church (Winners’ Chapel) ni Ṣagamu laarin ọdun 2002 si 2004, to si tun jẹ alakoso ẹgbẹ afadurajagun ti Living Faith church lọdun 2005 si 2007.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI