Alaṣẹ Adron Homes, Aarẹ EmmanuelKing lo n ṣọjọọbi lonii ọjọ keji, oṣu kẹrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 2, 2024

Alaṣẹ Adron Homes, Aarẹ EmmanuelKing lo n ṣọjọọbi lonii ọjọ keji, oṣu kẹrin


Bi eeyan kan ba n ko ipa ribiribi lawujọ, paapaa lorileede Naijiria lasiko yii, o yẹ ka ki iru ẹni bẹẹ, ka si yin lọgọ ẹnu.
 
Bi wọn ba si n sọ nipa awọn to sọ iṣẹ ile ikọ ati ilẹ rira di irọrun fawọn araalu lasiko yii, odu ni Aarẹ Adẹtọla EmmanuelKing, kii ṣaimọ foloko.
 
Iru awọn asiko bayii si lo yẹ lati maa fi gbe oṣuba kare fawọn akikanju to n ko ipa rere laarin ilu.
 
Lonii, ọjọ keji, oṣu kẹrin ni ọjọ ibi alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited, Aarẹ Adetọla EmmanuelKing, ti gbogbo awọn eeyan kaakiri agbaye si n ki ku oriire.

Eyi lo mu ki ileeṣẹ iwe iroyin AWIKONKO naa jade lati ki Aarẹ EmmanuelKing ku ayẹyẹ ọjọ ibi to n ṣe lonii, ti a si n gbadura pe ki Ọlọrun tubọ fun un ni ẹmi gigun ati alaafia lati jeere gbogbo iṣẹ rere rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI