Gbogbo agbegbe to wa nipinlẹ Kwara ni yoo jẹ igbadun omi ẹrọ igbalode lasiko yii - Ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 2, 2024

Gbogbo agbegbe to wa nipinlẹ Kwara ni yoo jẹ igbadun omi ẹrọ igbalode lasiko yii - Ijọba


Ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ omi igbalode nipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo agbegbe ati igberiko to wa nipinlẹ naa patapata ni yoo jẹ anfaani omi ẹrọ igbalode.
 
Awọn alakoso naa lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii, pẹlu ileri wi pe awọn ti ọpa omi wọn ti bẹ  ni wọn yoo ṣatunṣe rẹ lai fi asiko ṣofo.
 
Ninu atẹjade ti Alao Saad buwọ lu laipẹ yii lorukọ ọga rẹ, Onimọ ẹrọ Shehu Umar, o ni gbogbo awọn agbegbe ati igberiko ti ọpa omi wọn ko gba ki wọn ti n wa iyanju si, ki awọn naa le jẹ igbadun ijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI