Ẹ gbadura fun Naijiria - Alaṣẹ Adron gbawọn musulumi lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, April 10, 2024

Ẹ gbadura fun Naijiria - Alaṣẹ Adron gbawọn musulumi lamọran


Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited lorileede Naijiria, Aarẹ Adetọla EmmanulKing ti gba awọn musulumi jakejado orileede yii lamọran lati gba ifẹ, iṣọkan ati alaafia laaye bi wọn ṣe n pari aawẹ Ramadaani.

Aarẹ Adetọla lo gbe ipe yii jade loni, Ọjọru tii ṣe ọjọ ọdun Itunu Aawẹ Ramadaani ti ọdun 2024.

Ninu atẹjade to fi ranṣẹ sawọn akọroyin, Aarẹ Adetọla sọ pe ki awọn musulumi lo anfaani aawẹ yii lati yago fun ẹṣẹ ati awọn iwa ti ko le fi ogo fun Allah to yan aawẹ ọhun.
 
Bakan naa lo ni ki wọn ma ṣe dakẹ adura fun orileede Naijiria, paapaa lasiko ipenija eto ọrọ aje yii.

Ọtun Aṣiwaju Onigbagbọ tilẹ Rẹmọ naa tun sọ pe ẹsin Islam, gẹgẹ bo ṣe n pokiki alaafia ati ifẹ, o ni ki awọn ẹlẹsin naa fi ara jin fun awọn itọni ẹsin naa, paapaa fun itẹsiwaju ati idagbasoke ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI