Kẹhinde Ọnasanya di olori awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 9, 2024

Kẹhinde Ọnasanya di olori awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti kede Ọgbẹni Kẹhinde Olufẹmi Ọnasanya gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ naa, to si ni iṣẹ rẹ bẹrẹ loju ẹsẹ lai fi asiko ṣofo.

Ninu atẹjade ti akọwe ijọba ipinlẹ naa, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi fi sita, o ni Ọnasanya ni yoo gba ipo lọwọ Ọgbẹni Kọlawọle Fagbohun toun n fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba 

Titi digba ti wọn fi yan Ọnasanya, oun ni akọwe agba nileese Bureau of Political Affairs and Administration. 

Inu oṣu kejila, ọdun 1993 ni Ọnasanya darapọ mọ iṣẹ ijọba pẹlu ipele kẹjọ, to si ṣiṣẹ takuntakun to fi de ipele kẹtadinlogun.

Ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 ni Ọnasanya di akọwe agba.

Ogbontarigi to tun jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa iṣẹ iroyin ati alabojuto ni ọkunrin naa, to si tun jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ loriṣiriṣi bii ẹgbẹ akọroyin ati Nigerian Institute of Public Relations. 

O ti ṣiṣẹ loriṣiriṣi ẹka ileeṣẹ ijọba bii Ministry of Special Duties and Inter-Governmental Affairs ati Bureau of Political Affairs and Administration.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI