Gomina AbdulRazaq bawọn ara Ọffa kẹdun ọja Owode to jona - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 3, 2024

Gomina AbdulRazaq bawọn ara Ọffa kẹdun ọja Owode to jona


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba gbogbo awọn araalu Ọffa, paapaa awọ ọlọja kẹdun lori ọja Owode to jona lojiji.
 
Gbajugbaja ọja Owode ni iroyin fi to wa leti pe o jona di eeru, nigba ti ina deedee ṣẹyọ, ti ko si sẹni to le sọ pato bo ṣe ṣẹlẹ.
 
Gomina sọ pe ajalu nla ṣeni ni kayeefi, to si bani lọkan jẹ pupọ ni iṣẹlẹ ijamba ina ọhun.
 
O ni awọn aṣoju ijọba lati ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ti ṣabẹwo sibi ijamba ina ọhun, to si ni wọn yoo ṣakọsilẹ gbogbo ọja ati dukia to jona, lati le dide iranlọwọ fun wọn.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe iṣẹlẹ yii yoo tun ta awọn araalu ji pepe, lati maa kiyesi nipa awọn ohun to le ṣokunfa ati akoba fun iru iṣẹlẹ bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI