Ali Ciroma, Aarẹ ẹgbẹ NLC tẹlẹ jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 3, 2024

Ali Ciroma, Aarẹ ẹgbẹ NLC tẹlẹ jade laye


Aarẹ tẹlẹri fẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti Nigeria Labour Congress (NLC), Ali Ciroma ti jade laye.
 
Ciroma ni iroyin fi to wa leti pe o jade laye ni ọsibitu awọn olukọni ti Maiduguri, iyẹn University of Maiduguri Teaching Hospital, Maiduguri, ipinlẹ Borno lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọsẹ yii.
 
Ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe naa, ẹni to tun jẹ akọwe fẹgbẹ awọn akọroyin nipinlẹ Borno, Ali Ibrahim Ciroma lo kede iroyin iku baba naa ninu atẹjade to fi lede lonii.
 
“Pẹlu ibanujẹ ọkan ni mo fi n kede iku Kọmureedi Ali Ciroma, aarẹ tẹlẹri fẹgbẹ oṣiṣẹ Nigeria Labour Congress.
 
“Irọlẹ oni ni iṣẹlẹ aburu naa waye ni University of Maiduguri Teaching Hospital.
 
“Ọla tii ṣe Ọjọru ni eto isinku yoo waye laago mẹrin irọlẹ ni ile rẹ to wa ni ojule keje akọkọ, opopona  Galadima, nitosi Muhammadu Shuwa Memorial Hospital (Nursing Home), Maiduguri”.
 
Aarin ọdun 1984-1988 ni Oloogbe naa jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, lasiko iṣakoso ologun ti Ibrahim Babagida.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI