Ọwọ EFCC tẹ ọmọ 'Yahoo' mẹrinlelaadọrin (74) l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 2, 2024

Ọwọ EFCC tẹ ọmọ 'Yahoo' mẹrinlelaadọrin (74) l'OgunKo din ni afurasi ọmọ Yahoo mẹrindinlaadọrin ti ọwọ palaba wọn segi kaakiri ipinlẹ Ogun laipẹ yii.

Gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka ti ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ṣe sọ, wọn ni agbegbe ọtọọtọ lọwọ ti tẹ wọn.

Agbegbe GRA to wa niluu Ṣagamu, ipinlẹ Ogun lọwọ palaba wọn ti segi lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun yii, gẹgẹ bi aṣe gbọ.
 
Lara awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn ni mọto bọginni meje, kọmputa alagbeka mẹta, foonu olowo nla mẹrinlelọgọfa (124), geemu PS mẹta, ọkada meji ati awọn ẹru ofin miran.
 
Ajọ EFCC to fidi iroyin ọhun mulẹ jẹ ko di mimọ pe gbogbo wọn yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI