O ma ṣe o! Wọn tọpinpin Khalid pa l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 11, 2024

O ma ṣe o! Wọn tọpinpin Khalid pa l'Abuja


Ọdọmọkunrin kan la gbọ pe awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko tii mọ idanimọ wọn titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tọpinpin, ti wọn si yinbọn pa a danu niluu Abuja.
 
Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii la gbọ pe awọn agbọn naa ti wọn pe ni agbanipa ṣeku pa ọdọmọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Khalid Bichi.

Agbegbe Maitama to gbajumọ daadaa niluu Abuja la gbọ pe wọn pa Khalid danu si.

Oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ ipawo-wọle, iyẹn Federal Inland Revenue Service, FIRS ni wọn pe Khalid ko too ku.
 
AWIKONKO gbọ pe Khalid fẹ lọ ra ounjẹ ni lasiko ti wọn yinbọn pa a.
 
Lara awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ la gbọ pe wọn gbiyanju lati doola ẹmi rẹ, nigba ti wọn gbe e digbadigba wọ ọsibitu jẹnẹra to wa ni Maitama, nibi to pada ku si patapata.

Agbẹnusọ ọlọpaa ilu Abuja, SP Josephine Adeh, sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lati mọ awọn pa ọdọmọkunrin naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI