Ẹ dẹkun iwa jagidijagan, ki ẹ si gbajumọ eto ẹkọ - Boakai, ọmọ Aarẹ Liberia gba awọn ọdọ ipinlẹ Ogun lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 29, 2024

Ẹ dẹkun iwa jagidijagan, ki ẹ si gbajumọ eto ẹkọ - Boakai, ọmọ Aarẹ Liberia gba awọn ọdọ ipinlẹ Ogun lamọran


Tamba Boakai Jr, ọmọ Aarẹ orileede Liberia ti gba awọn ọdọ ipinlẹ Ogun lamọran lati jawọ ninu iwa ipa ati jagidijagan, eyi to le ba ọjọ ọla wọn jẹ.

O ni dipo iwa jagidijagan, ki wọn gbe iwa ọmọluwabi wọ lati gbajumọ eto ẹkọ to le gbe wọn de ibi giga lagbaye.

Tamba Boakai Jr lo sọrọ yii niluu Abẹokuta laipẹ yii, lasiko abẹwo to ṣe si aafin Olu Orile Ilawọ, Ọba Olusegun Alexander MacGregor to wa ni ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, oṣu diẹ sẹyin ni Ọba MacGregor lọ si orileede Liberia lati gbe oṣuba kare fun Aarẹ Joseph Boakai lori iṣẹ takuntakun to n ṣe nipa ilọsiwaju.

Nibẹ ni Oba MacGregor ti ṣe iranwọ nla fun ajọ alaanu ti Tamba Boakai da silẹ pẹlu owo ati awọn ileri miran.

Tamba Boakai ninu ọrọ rẹ sọ pe ẹmi imoore loun wa fi han pada si Ọba MacGregor.

O wa sọ pe iwa jagidijagan maa n ba ọjọ iwaju orileede jẹ ni, kii mu ilọsiwaju ba orileede.

Fun idi eyi, o ni ki awọn ọdọ gbogun ti awọn iwa to le fa ọwọ aago ilọsiwaju jẹ, ki wọn si gba alaafia laaye, ati pe eto ẹkọ ṣe pataki pupọ.

O ni ki wọn mu ọrọ eto ẹkọ lọkunkundun, eyi to pe gbe eeyan de ibi rere ti ko lero lagbaye.

Lara awọn to tun gba Boakai Jr lalejo ni Olori Ọmọlara MacGregor, awọn oloye ilu Orile Ilawọ, to fi mọ awọn ọdọ ati afẹnifẹre.

Ilu, orin, ijo ati awọn ohun aṣa ọlọkanojọkan ni wọn fi gba Boakai Jr lalejo.

Bakan naa ni Boakai Jr tun ṣabẹwo si Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ ati Olowu tilu Owu, Ọba Saka Matẹmilọla.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI