June 12: Ẹgbẹ oṣelu ADC ṣi ile ẹgbẹ tuntun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 14, 2024

June 12: Ẹgbẹ oṣelu ADC ṣi ile ẹgbẹ tuntun l'Abẹokuta


Ẹgbẹ oṣelu African Democrats Congress, ADC ti ṣi ile ẹgbẹ wọn tuntun silii Abẹokuta ipinlẹ Ogun.

Lọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 2024 ni awọn agbaagba ẹgbẹ naa lapapọ, paapaa nipinlẹ Ogun parapọ lati ṣi ile ẹgbẹ naa si agbegbe Itoko to wa niluu Abẹokuta.

Nibẹ naa la tun ri awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu bii ZLP, YPP, APM  ati awọn miran ni wọn wa nibẹ lati yẹ wọn si.

Nigba to n sọrọ, alaga apapọ fẹgbẹ oṣelu ADC, Ralph Nwosu sọ pe lara awọn igbesẹ lati gba iṣakoso ipo to ga julọ lọdun 2027 ni awọn ti bẹrẹ yii.

O ni o ṣeni laanu wi pe Aarẹ Bọla Tinubu ko ṣiṣe adari gidi pẹlu bo ṣe mu ọrọ Oloogbe Moshood Kashimawo Olawale Abiola nipa bo ṣe n tukọ orileede Naijiria.
 
Nwosu sọ pe Tinubu gẹgẹ bii Aarẹ NADECO kii ṣe aṣoju rere si ohun ti Abiọla ja fun lori ọrọ oṣelu awarawa ti June 12 ko to di pe o jade laye.
 
O ni kaka ki Tinubu jẹ ki gbogbo nnkan dẹrun fun araalu, niṣe ni eto ọrọ aje dẹnukọlẹ, ti ọwọngogo si wa, koda ti ebi, iṣẹ ati oṣi tun n ba araalu finra.
 

Bẹẹ lo sọ pe ọrọ eto aabo ko ṣee sọ pẹlu bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe kaakiri

Siwaju sii lo ni lọdun 2027, awọn yoo gba iṣakoso lọwọ ṣakoso APC kaakiri Naijiria, ti yoo si ya gbogbo aye lẹnu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI