Meghan kọ lẹta idupẹ nla si Oluwo, o loun tun n bọ laipẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 2, 2024

Meghan kọ lẹta idupẹ nla si Oluwo, o loun tun n bọ laipẹ


Iyawo Ọmọọba Harry, Meghan Markle ti kọ lẹta idupẹ nla si Oluwo niluu, Ọba AbdulRọsheed Adewale Akanbi lori bo ṣe gba wọn lalejo lọjọsi.

Meghan ninu lẹta idupẹ to kọ ranṣẹ si Oluwo lọjọ kẹtalelogun, oṣu karun-un, ọdun 2024 lo ti sọ pe inu oun dun pupọ fun awọn asiko toun lo ni Naijiria, paapaa pẹlu Oluwo.

Bẹẹ lo tun sọ pe oun dupẹ gidigidi fun orukọ nla 'Adetokunbọ' ti Oluwo fun oun ati ọkọ oun, to si l'awọn mọ riri rẹ gidigidi.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Duke ati Duchess of Sussex gẹgẹ bi wọn ti maa n pe wọn ṣabẹwo ọlọjọ mẹta si Naijiria.

Abẹwo ọhun ni lati bu ọla ati ẹyẹ fun awọn ọmọ ogun ti wọn farapa loju ogun, ki wọn si le mọ pe gbogbo agbaye lo mọ riri wọn.

Oluwo si wa lara awọn ọba Naijiria ti wọn pe sibi apejẹ to waye ni otẹẹli Delborough, Ikoyi nipinlẹ Eko.

Nibẹ lo si ti fun awọn mejeeji ni orukọ 'Adetokunbọ', to tun fi aṣọ Ofi olowo iyebiye ati ilẹkẹ oye ta wọn lọrẹ.


Ninu lẹta idupẹ ti Meghan Markle kọ ranṣẹ, o ni
"Ẹ ṣeun bi ẹ ti ṣe fi ifẹ gba wa lalejo wa si Naijiria. Inu mi dun, mo si mọ riri ibukun orukọ ibilẹ Yoruba nni, Adetokunbọ.

"Mo mọ riri orukọ naa, mo si dupẹ fun igbagbọ ti ẹ ni ninu mi lati gbe orukọ naa pẹlu oore ọfẹ ati iwa ọmọluwabi.

"Abẹwo wa si Naijiria ṣe pataki pẹlu awọn idi to pọ, ati pe ko kere rara nitori pe o tun fun mi ni anfaani lati wo, ki n si mọ ibi ti mo ti ṣẹ wa, eyi to tun lọ sọdọ awọn ọmọ wa.

"A tun n foju sọna lati pada wa sile lọjọ kan laipẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI