Iyanṣẹlodi: Akpabio, Abass ati awọn alẹnulọrọ ninu ijọba wọle ipade pajawiri pẹlu apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 2, 2024

Iyanṣẹlodi: Akpabio, Abass ati awọn alẹnulọrọ ninu ijọba wọle ipade pajawiri pẹlu apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ


Bo ṣe n ku wakati diẹ ki eto iyanṣẹlodi ti apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, NLC ati TUC kede laipẹ yii bẹrẹ, awọn alẹnulọrọ ninu ijọba ti wọle ipade pajawiri pẹlu wọn lati wa ọna abayọ.

Awọn alakoso ile igbimọ aṣofin agba ati awọn minisita marun-un la gbọ pe wọn bẹrẹ ipade pajawiri pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lojuna lati wa nnkan ṣe si ọrọ owo oṣu tuntun ti wọn n beere fun.

Bẹẹ si ni lati so iyanṣẹlodi ti wọn fẹẹ funle lọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu kẹfa to wọle de yii rọ.

Awọn alakoso ile igbimọ aṣofin agba ni wọn pe ipade pajawiri yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Lara awọn to si wa nibẹ ni akọwe ijọba apapọ, Sẹnetọ George Akume; olori awọn oṣiṣẹ aarẹ, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila; minisita f'ọrọ eto iṣuna, Ọmọwe Wale Ẹdun; minisita f'ọrọ eto iṣuna ati agbekalẹ, Atiku Bagudu; minisita f'eto iṣẹ ode, Nkiruka Onyejiocha.

Awọn miran ni minisita f'ọrọ eto iroyin ati ilanilọyẹ, Mohammed Idris; minisita f'ọrọ eto iṣẹ agbẹ ati idagbasoke igberiko, Ọmọwe Aliyu Sabi Abdullahi ati olori awọn oṣiṣẹ ijọba lapapọ, Fọlaṣade Yẹmi-Ẹsan.

Bakab naa ni alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ti NLC lapapọ, Kọmureedi Joe Ajaero; alaga agba fẹgbẹ oṣiṣẹ TUC, Festus Osifo ati awọn oloye ẹgbẹ ni ko gbẹyin nibi ipade naa.

Díẹ ree lara awọn aworan ibi ipade naa...No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI