Iyalẹnu nla gba a ni lẹta ikọwe fiṣẹ silẹ ti amugbalẹgbẹ Sẹnetọ Salihu Mustapha to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kwara, Jamiu Abdulmumeen Okolo lati fiṣẹ silẹ jẹ fun ọpọ awọn to rii.
Kii ṣe bi Jamiu Abdulmumeen Okolo ṣe kọwe fiṣẹ silẹ lo n ya ọpọ awọn eeyan lẹnu, bi ko tun ṣe ti awọn ẹsun ọdalẹ to fi kan agba oloṣelu naa, to si lo n ṣiṣẹ tako Aarẹ Bọla Tinubu.
Odu ni Jamiu Abdulmumeen Okolo, kii ṣaimọ foloko, ẹni to jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Ṣẹnetọ Salihu Mustapha lori ọrọ to nii ṣe pẹlu kiko awọn ọdọ jọ.
Ọjọbọ, ọsẹ yii ni lẹta naa jade sita, nibi to ti sọ oriṣiriṣi to nii ṣe pẹlu ọrọ oṣelu.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ kinni, oṣu Kẹsan, ọdun 2023 ni Sẹnetọ Mustapha yan Okolo, gẹgẹ bi alabaṣiṣẹpọ rẹ.
Ṣugbọn ọkunrin naa ninu lẹta to kọ, o ṣalaye pe oun ko faramọ oṣelu ti ọga oun naa n ṣe, ti ko si ba oun lara mu.
Lẹta naa ree, ẹ ka a lẹkunrẹrẹ...
No comments:
Post a Comment