Ileeṣẹ eleto aabo nipinlẹ Ogun, Ogun State Community, Social Orientation, and Safety Corps, ti wọn n pe ni So-Safe Corps, ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ajoji mẹrin kan ti wọ orileede Naijiria lọna aitọ.
Orileede Cameroon ati Chad ni awọn atọhunrinwa mẹrin naa ti wọ Naijiria, ati pe ipinlẹ Ogun ni wọn gba wọle.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ So-Safe Corps, Moruf Yusuf fi sita lonii ọjọ Ẹti, Furaidee, o sọ pe ọjọ kẹtala tii ṣe Ọjọbọ, ọsẹ yii lọwọ tẹ awọn mẹrẹẹrin ni nnkan bi agogo mẹjọ owurọ.
Yusuf sọ pe niṣe ni awọn eeyan naa wọ ọkọ taisi to n lọ si agbegbe Lafenwa niluu Abeokuta, nibi ti aṣiri wọn ti tu.
O ni awọn kan lo ta ikọ ọtẹlẹmuyẹ wọn lolobo, ko to di pe wọn sare lọ pade wọn, ko to di pe wọn bọ silẹ ninu ọkọ taisi ti wọn wọ, ti wọn si rọwọ to wọn.
Agbẹnusọ naa sọ pe lasiko ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo nipa bi wọn ṣe wọ Naijiria, o ni meji ninu wọn ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Cameroon jẹwọ pe awọn ti n gbe niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo lati bi oṣu mẹrin sẹyin.
Wọn ni latigba naa lawọn ti n reti awọn meji to ku ti wọn wa lati Chad, ati pe niṣe lawọn wa tẹlẹ de awọn yooku ko to di pe wọn ranṣẹ pe wọn.
Awọn mẹrin naa ni Dorooumouna Brosia, ẹni ọdun mẹtalelogun, ọmọ ilẹ Cameroon to jẹ olori wọn; Hassan Bukhari, toun naa jẹ ọmọ Cameroonian; Saleh Sinine Sakhair, ọmọ ilẹ Chad to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ati Mahamat Moudaina, ọmọ ọdun mẹtalelogun toun naa jẹ ọmọ Chad.
Moudaina sọ pe ẹgbọn oun to ti n gbe niluu Ibadan tipẹ, ẹni to n ṣiṣẹ ni Lafẹnwa, lo pe awọn lati maa bọ nipinlẹ Ogun. Wọn lawọn fẹ wa a ṣiṣẹ, ki awọn si kọ ede oyinbo daadaa.
Oga agba fun ileeṣẹ naa, Soji Ganzallo fi ẹdun ọkan rẹ han lori bawọn ajoji ṣe n wọ Naijiria lọna aitọ, to si ni eyi le ṣakoba fun eto aabo ati ilera, ati pe oniruuru iwa ọdaran ni awọn ajoji naa le wu.
Ganzallo ti wa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti fa awọn mẹrẹẹrin le ileeṣẹ aṣọbode orileede Naijiria lọwọ lati tẹsiwaju iwadii, ki wọn si gbe igbesẹ to yẹ labẹ ofin.
No comments:
Post a Comment