Ileeṣẹ to n ri sọrọ ilana ati eto ilẹ nipinlẹ Kwara, Kwara State Geographic Information Services (KWGIS) ti fidi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni tabi ileeṣẹ yoowu to ba fẹẹ kọ omiruuru ile tabi dukia sori ilẹ gbọdọ gba iwe aṣẹ ijọba.
KWGIS ṣalaye pe eyi yoo ṣe iranlọwọ to pọ fun ilana lilo ilẹ daadaa, eyi ti wọn pe ni 'Land Use Act'.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin ileeṣẹ KWGIS, Abdulrazaq Yusuf fi sita, o ni ileeṣẹ naa ti bẹrẹ oriṣiriṣi eto ipolongo lati la awọn araalu lọyẹ, lati ni imọ kikun nipa ofin ilẹ.
O ni eyo ilanilọyẹ ti waye lori redio ati tẹlifiṣan kaakiri ipinlẹ naa, leyi ti yoo jẹ ki araalu mọ pataki ilana ofin ilẹ ati ile kikọ.
"Eyi ṣe pataki. Nibi ti awọn eeyan tabi ileeṣẹ, ajọ ti ijọba ti n gboju fo o, tabi kọ awọn amuyẹ pataki eyo ilana ofin idagbasoke maa silẹ, a ni ojuṣe ti kii ṣe lati da wọn duro nikan, bi ko ṣe lati tun jẹ ki wọn san owo itanran to yẹ," alaga ileeṣẹ KWGIS, AbdulKareem Sulyman sọ eyi lọjọ Abamẹta to kọja.
Sulyman sọ pe awọn eeyan gbọdọ kọkọ gba iwe aṣẹ ko to di pe wọn bẹrẹ ohunkohun lori ilẹ wọn, ati pe gbogbo iṣẹ akanṣe ijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ ni wọn ni iwe aṣẹ yii.
Bẹẹ lo ni awọn ti rọ gbogbo awọn agbaṣẹṣe lati ṣe ohun to tọ, ko to di pe wọn bẹrẹ ohunkohun.
O ṣalaye pe idagbasoke naa ni yoo dẹkun ile wiwo, ati pe ijọba yoo ṣabojuto ilana ti yoo dẹkun ile wiwo lọjọ iwaju.
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe awọn ileeṣẹ bii Peace Pharmaceutical to wa loju ọna Asa Dam ati HRA to wa loju ọna Lubcon ni wọn n kọ dukia rẹpẹtẹ lai gba iwe aṣẹ to yẹ, to si ni ijọba ti ti wọn pa, titi digba ti wọn yoo fi ṣe ohun to yẹ.
No comments:
Post a Comment