Ijọba Kwara bẹrẹ kikọ ileeṣẹ eto idajọ alaja mẹfa tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 9, 2025

Ijọba Kwara bẹrẹ kikọ ileeṣẹ eto idajọ alaja mẹfa tuntun


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fa kikọ ileeṣẹ eto idajọ alaja mẹfa tuntun fun awọn agbaṣẹṣe.

Ileeṣẹ eto idajọ tuntun naa, eyi ti wọn pe ni 'Legacy Court House Project' lo jẹ agbekalẹ Gomina AbdulRazaq, pẹlu erongba lati mu idagbasoke ba eto idajọ nipinlẹ naa.

Nigba to n fa iwe aṣẹ akanṣe iṣẹ idagbasoke naa le awọn agbaṣẹṣe lọwọ laipẹ yii niluu Ilorin, Kọmiṣanna feto ile kikọ ati idagbasoke agbegbe, Ọmọwe Segun Ogunsola sọ pe igbesẹ naa yoo mu adinku ba wahala ilana iṣẹ eto idajọ nipinlẹ Kwara.

Ọmọwe Ogunsola sọ pe yatọ si yara idajọ mẹjọ ti yoo wa ninu ọgba naa, bẹẹ ni ọfiisi, gbọngan ipade ati igbalejo, yara ikawe ati bẹẹbẹẹlọ ko nii gbẹyin nibẹ.

Opopona Ahmadu Bello to wa niluu Ilorin ni wọn ya sọtọ fun kikọ ileeṣẹ eto idajọ tuntun naa.

Kọmiṣanna naa sọ pe akọkọ iru rẹ ree nilẹ Afrika, pẹlu erongba lati mu ayipads ba gbogbo ẹka nipinlẹ naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI