Gomina Oyebanji sọrọ lori ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla tawọn Fulani darandaran pa l'Ekiti nitori ibalopọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 14, 2025

Gomina Oyebanji sọrọ lori ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla tawọn Fulani darandaran pa l'Ekiti nitori ibalopọ


Gomina Biodun Oyebanji tipinl]e Ekiti ti ṣapejuwe iku ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan, Faith Moses, tawọn Fulani darandaran pa danu nitori ti ko gba lati jẹ ki wọn ba oun lajọṣepọ.
 
Ilu Emure Ekiti niṣẹlẹ ọhun waye laipẹ yii.
 
Awọn afurasi meji kan tọwọ tẹ, Bashir Alaba, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Mohammad Jamiu, ẹni ọdun mẹrindinlogoji la gbọ pe wọn fẹẹ fipa ba Faith lajọṣepọ, ṣugbọn ti ko gba fun wọn.
 
Bi Faith ko ṣe gba fun wọn, lo jẹ ki wọn ṣeku pa a, ti wọn si na papa bora.

Oyebanji, lasiko abẹwo ibanikẹdun to ṣe lọ sile mọlẹbi oloogbe naa l'Ọjọru, ọsẹ yii, o sọ pe adanu nla ni iṣẹlẹ ọhun jẹ, ati pe awọn ko nii jẹ ki iku Faith lọ gẹgẹ bi ejo to kọja lori apata.
 
Igbakeji gomina, Monisade Afuye to ṣoju gomina nibi abẹwo ibanikẹdun naa sọ pe igbesẹ ti n lọ lati dawọ gbogbo iba buruku naa duro.
 
O ni kii ṣe pe awọn ko mọ nipa oniruuru iwa ipaniyan to n lọ lawọn agbegbe igberiko to sunmọ ẹnubode ipinlẹ naa, to si lawọn n gbiyanju lati koju iṣoro naa, sibẹ, o jẹ ko di mimọ pe gbogbo rẹ yoo dopin laipẹ.
 
O wa rọ araalu lati maa wa ni ojufo lori awọn oju ajoji to ba n kọja lagbegbe wọn, ki wọn si fi to ileeṣẹ eleto aabo leti.
 
Bẹẹ lo ni ibudo ikọ ọmọ ogun to wa lopopona Emure-Eporo-Emure Ile to lati dena awọn ajinigbe ti wọn gba ẹnubode wọle sipinlẹ Ondo.
 
Nigba toun naa n sọrọ, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Joseph Eribo,  sọ pe ọlọpaa agbegbe ti jẹ itẹwọgba kaakiri agbaye, to si ni awọn ọlọpaa oun yoo bẹrẹ sii ni ibaṣepọ to dan mọnran papọ pẹlu awọn alẹnulọrọ laarin ilu lati gbogun ti awọn ọdaran kaakiri.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa, Sunday Abutu sọ pe niṣe ni wọn pa Faith nipakupa, pẹlu bi wọn ṣe fi ọbẹ yọ ikọfun ọrun rẹ silẹ, nibi to ti n ba wọn jijakadi, lasiko ti wọn fẹẹ fipa ba a laṣepọ.
 
“Awọn afurasi meji naa, Bashir Alaba, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Mohammad Jamiu, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ni ọwọ tẹ nitosi ibi iṣẹlẹ naa, pẹlu ada meji ti igbagbọ wa pe ohun ni wọn lo lati fi pa Faith. Iwadii ṣi n lọ lọwọ,” Abutu ṣalaye.
 
"L'ọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun 2025, ni nnkan bi agogo meje kọja iṣẹju mẹwaa alẹ, ẹnikan to n jẹ Toyin Moses ti adugbo Odo-Emure, Emure-Ekiti, sare wọ teṣan ọlọpaa ẹkun Emure, to si ni ki ọkọ oun, Joshua Moses too rin irin ajo lọ si Oka Akoko nipinlẹ Ondo, o sọ fun Faith Moses lati lọ wo pakute toun dẹ sinu oko loju ọna Okeseri.
 
“Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni nigba ti Faith n lọ sinu oko naa, niṣe lo mu aburo rẹ to jẹ ọmọ ọdun marun-un dani, iyẹn Testimony Moses. O ni ọmọ naa to raaye na papa bora lo wa sọ pe awọn ọkunrin meji kan tẹle awọn, ti wọn si lawọn fẹẹ ba Faith laṣepọ tabi ki wọn pa a.
 
“O kọ ibalopọ, eyi lo si jẹ ki wọn fipa dẹmi rẹ legbodo, ti wọn si yọ ikọfun rẹ bọ silẹ, koda ti wọn tun ge apa rẹ sọnu.
 
“Bi a ṣe gbọ ẹsun yii la ti tete gbe igbesẹ, ti a si de ibi iṣẹlẹ naa, nibi iwadii lọwọ ti tẹ awọn afurasi meji yii,” agbẹnusọ naa ṣalaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI