Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alagba Adebanjọ jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 14, 2025

Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alagba Adebanjọ jade laye


Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre lorileede Naijiria, Alagba Ayọdele Adebanjọ ti jade laye.
 
Baba naa ni iroyin fi to wa leti pe o jade laye lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun-un loni, ọjọ Ẹti, Furaidee.
 
Ọkan lara awọn mọlẹbi oloogbe lo fidi iroyin naa mulẹ.
 
O sọ pe ile ti baba Adebanjọ n gbe lagbegbe Lekki nipinlẹ Ekoo lo dakẹ si laarọ oni.
 
Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI